byOmolarami Owotomose

Orimi Afiire 

 

 

Awon agba Yoruba ni "Ori lababo ka fi orisa sile"

Ori mi tetela,

Ki ori olola ma se pe o ran nise

Orimi afiire

 

Ori lo mo ibi kadara n gbe ese re

Nje kani pe moti beere lowo ori mi

N ba ti wa lawujo lobaloba laise laala

 

Nje kani mo beere lowo ori

N ba ti mo ore yato so eni a nsafun

Nje kani mo beere lowo ori

N ba ti mo alabaro yato so amoniseni

 

Nje kani mo ti bo ori mi

Iba ti gbe alawo ire komi

Nje kani mo ti fi ti ori mi se

N ba ti bori alaroka

Aseni tan tun ba ni daro

 

Ori segbe Lehin Olajumoke oniburedi

Aje file re se ibugbe lalairo tele

Ori ti Mr. Spell Buhari lehin

Okiki re kan lairo tele

 

Ori a so talika di olola losan gangan

Ori a so eni a ti ropin

Di orisa akunle bo ni iseju aaya

Ori ni n yan ipin

Ori ni n pin ire

 

Ori mi ori ola

Ori mi afire

Orimi yan fun mi

Ki n ma se akobata fun egbe

 

Ori mi gbe mi

ki aye ma tipa se re ri adeda mi fin

Ori mi gbe mi Ko ire

Ori mi gbe ire komi

Ki aye ma tipa se re soro odi si aseda mi.

 

#30DaysWritingChallenge

 

 

 

 


Share this with friends