byOmolarami Owotomose

Olaju De!!!  

 

 

Olaju de a gbagbe isese

Olaju de a gbagbe asa ati ise wa

Laye ojosi omode kiigboju soke wo agba

Laye ojosi bi agba ba n soro

Omode a gbe je

 

Olaju de a gbagbe awon eso ori ati ara

Ti igba ojoun

Olaju de a gbagbe awon irun ori bii

Suuku, adimole, kojusoko, ipako elede, koroba,

Orisa bunmi, adiseyin atii beebe lo.

 

Olaju de sisi rasile di oge lawujo awon olomoge wa

Omiran a le irun moju dabi oku tin n be nipopo

Olaju de awon odomokunrin so yeri ni eti ati imu di eso oge

Ina loju Ina Lenu afi bii ti sango.

 

Olaju de awon ewe kii dide fun agba lati joko mo

Awon odo ko Latin ni iteriba ati iforiti

Olaju de ero ibanisoro so ori aye kodo

Awon odo a si mu agbalagba bu bii eni layin

 

Olaju dakun ro ola orile ede yi

Olaju dakun fi ohun ti o tona ko awon odo orile yi.

 

 

#30DaysWritingChallenge

 

 

 

 

 

 


Share this with friends

Similar Posts